Sáàmù 22:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Má ṣe jìnnà sími,nítorí pé ìyọnu sún mọ́ tòsíkò sì sí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;àwọn màlúù alágbára Báṣánì rọ̀gbà yí mi ká.

13. wọ́n ya ẹnu wọn, si mi bí i kìn-nìún tí ń dọdẹ kirití ń ké ramúramù.

14. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé Rẹ̀.Ọkàn mi sì dàbí i ìda;tí ó yọ́ láàrin inú un mi.

15. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mí sì ti lẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

Sáàmù 22