Sáàmù 22:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,àní sí igbe àwọn asọ̀ mi?

2. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:àti ní òru èmi kò dákẹ́.

3. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;ẹni tí ó tẹ ìyìn Ísírẹ́lì dó;

4. Àwọn babańlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un Rẹ;wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

Sáàmù 22