Sáàmù 19:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ,ju góòlù tí o dára jùlọ.wọ́n dùn ju oyin lọ,Àti ju afárá oyin lọ.

11. Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

12. Ta ni o lé mọ àṣìṣe Rẹ̀?Dáríjìn mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

13. Wẹ ìrànsẹ́ Rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;Má ṣe jẹ kí wọn kí ó jọba lórí mi.Nígbà náà ní èmí yóò dúró ṣinṣin,èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

Sáàmù 19