Sáàmù 18:42-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.

43. Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ́ èdè;àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí.

44. Wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n gbọ́ gbàmí;àwọn ọmọ àjèjì yóò fi ẹ̀tàn tẹríba fún mi.

45. Àyà yóò pá àlejò;wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.

46. Olúwa wà láàyè! Olùbùkún ni àpáta mi!Gbígbé ga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

Sáàmù 18