1. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
2. Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.Òun ni àpáta ààbò àti agbára ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3. Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,a ó sì gbàmí lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta à mi.