Sáàmù 143:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mijẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ dídáradarí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

11. Nítorí orúkọ Rẹ, Olúwa, sọ ayé mi di ààyè;nínú òdodo Rẹ mú mi jáde nínú wàhálà.

12. Nínú ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀ta mi kúrò,run gbogbo àwọn ọ̀tá mi,nítorí èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ.

Sáàmù 143