1. Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,yọ mi lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà nì;
2. Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;nígbàgbogbo ní wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
3. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ́ ní abẹ́ ètè wọn.
4. Olúwa, pa mí mọ́ kúròlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nìẹni tí ó ti pinnu Rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú