Sáàmù 136:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Òsùpá àti ìràwọ̀ láti jọba òru;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

10. Fún ẹni tí ó kọlu Éjíbítì lára àwọn àkọ́bí wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

11. Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

12. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

13. Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

14. Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Sáàmù 136