15. Èmi yóò bùkún oúnjẹ Rẹ̀ púpọ̀ púpọ̀:èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà Rẹ̀ lọ́rùn.
16. Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlúfáà Rẹ̀:àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
17. Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwọ Dáfídì yọ̀,èmi ti ṣe ìlànà fítílà kan fún ẹni òróró mi.
18. Àwọn ọ̀tá Rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:ṣùgbọ́n lára Òun tìkararẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.