Sáàmù 13:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sùn oorun ikú;

4. Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun Rẹ̀,”àwọn ọ̀ta mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

5. Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà;ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ.

6. Èmi ó kọrin sí Olúwa,nítorí ó dára sí mi.

Sáàmù 13