Sáàmù 125:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Síónì,tí a kò lè sí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé

2. Bí òkè ńlá ti yí Jérúsálẹ́mù ká,bẹ́ẹ̀ ní Olúwa yí ènìyàn káláti ìsinsìnyí lọ àti títí láéláé.

3. Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburúkì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;kí àwọn olódodo kí o máa bafi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Sáàmù 125