19. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi.
20. Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.
21. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-úntí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ.
22. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́.
23. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́nń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.
24. Òfin Rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.
25. Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀;pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ.
26. Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn;kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.
27. Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.
28. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.
29. Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tànfún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ.