Sáàmù 119:125-131 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

125. Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ; ẹ fún mi ní òyekí èmi lè ní òye òfin Rẹ

126. Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;nítorí òfin Rẹ ti fọ́.

127. Nítorí èmi fẹ́ràn àsẹ Rẹju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

128. Nítorí èmi kíyèsí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ Rẹ̀,èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

129. Òfin Rẹ̀ ìyanu ni:nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;ó fi òye fún àwọn òpè.

131. Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ.

Sáàmù 119