Sáàmù 119:118-122 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

118. Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

119. Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọyọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.

120. Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ

121. Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

Sáàmù 119