Sáàmù 119:113-116 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

113. Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.

114. Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

115. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!

116. Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

Sáàmù 119