12. Wọn gbá yìnìn yí mí ká bí oyin,ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
13. Ìwọ tì mi gidigidi kí ń lè subú,ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14. Olúwa ni agbára àti orin mi;ó si di ìgbàlà mi.
15. Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:“ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16. Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbé ga;ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”