Sáàmù 109:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwakí o le ge ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16. Nítorí kò rántí láti ṣàánú,ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíní sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.

17. Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí Rẹ̀:bi inú Rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ́ẹ̀ ni ki ó jìnnà sí ì.

18. Bí ó ti fi ègún wọ ará Rẹ̀ lásọ bí ẹ̀wùbẹ́ẹ̀ ni kí ó wá si inú Rẹ̀ bí omi

19. Jẹ́ kí o rí fún un bí aṣọ tí a dàbòó níara, àti fún àmùrè ti ó fi gbàjá nígbà gbogbo

Sáàmù 109