10. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódiTa ni yóò sìn mi wá sí Édómù
11. Ìwọ Ọlọ́run há kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njúnítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni
13. Nípaṣẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akinnítorí oun ó tẹ àwọn ọ̀ta wa mọ́lẹ̀.