Sáàmù 107:2-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí bayí, àwọnẹni tí ó ràpadà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

3. Àwọn tí ó kó jọ láti ilẹ̀ wọ̀nnìláti ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn,láti àríwá àti òkun wá.

4. Wọn ń rìn káàkiri ni ihà ni ibi tí ọ̀nà kò sí,wọn kòrí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tíwọn ó máa gbé

5. Ebi ń pa wọn, òùngbẹ gbẹ wọn,ó sì Rẹ̀ ọkàn wọn nínú wọn.

6. Ní ìgbà náà wọn kígbe sókèsí Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn

7. Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlútí wọ́n lè máa gbé

8. Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

9. Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́runó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa.

10. Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin,

11. Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo,

12. Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14. Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16. Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.

17. Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọnwọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn

18. Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹwọ́n sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ikú.

19. Nígbà náà wọn kígbe sí Olúwa nínúìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdàámú wọn

20. Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ara wọn sí dáó sì yọ̀ wọ́n nínú isà òkú.

Sáàmù 107