Sáàmù 105:32-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ó sọ òjò di yìnyín,àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn;

33. Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọnó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn.

34. Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé,àti kòkòrò ní àìníye,

35. Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run

36. Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,ààyò gbogbo ipá wọ́n.

37. Ó mú Ísírẹ́lì jádeti òun ti fàdákà àti wúrà,nínú ẹ̀yà Rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38. Inú Éjíbítì dùn nígbà tí wọn ń lọ,nítorí ẹ̀rù àwọn Ísírẹ́lí ń bá wọ́n.

Sáàmù 105