Sáàmù 104:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó bú omi rìn àwọn òkè láti iyẹ̀wù Rẹ̀ wá;a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èṣo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

14. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹàti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lòkí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:

15. Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan,àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà.

16. Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára,Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.

17. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.

18. Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.

19. Òsúpá jẹ àmì fún àkókòòòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀.

20. Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri.

21. Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọnwọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

22. Òòrùn ràn, wọn sì kó ara wọn jọ,wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ìhò wọn.

23. Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,àti sí làálàá Rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24. Iṣẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá a Rẹ.

25. Bẹ́ẹ̀ ni òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìṣàlẹ̀ láìníyeohun alàyè tí tóbi àti kékeré.

Sáàmù 104