Sáàmù 103:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹni tí o fi ohun dídara tẹ́ ọ lọ́rùnkí ìgbà èwe Rẹ̀ le di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6. Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fúngbogbo àwọn tí a nilára.

7. Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

8. Olúwa ni aláàánú àti olóore,ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbobẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé;

Sáàmù 103