22. Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àtiìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
23. Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀,ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24. Èmi sì wí pé;“Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.
26. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọnwọn yóò sì di àpatì.