Sáàmù 102:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.

17. Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18. Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

19. “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wáláti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé,

Sáàmù 102