Rúùtù 4:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16. Náómì sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.

17. Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì.

Rúùtù 4