Rúùtù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Bóásì gòkè lọ sí ẹnu ìbodè ìlú, ó sì jòkòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó sún mọ́ Elimélékì jùlọ, arákùnrin tí Bóásì ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Bóásì pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jokòó.” Ó sì lọ jokòó.

2. Bóásì sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbààgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí se bẹ́ẹ̀,

3. ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Náómì tí ó dé láti ilẹ̀ Móábù fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin wa, Elimélékì.

Rúùtù 4