Róòmù 11:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé.

26. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Ísírẹ́lì là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ní Síónì ni Olúgbàlà yóò ti jáde wá,yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jákọ́bù.

27. Èyí sì ni májẹ̀mú mi fún wọn.Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”

28. Nípa ti ìyìn rere, ọ̀ta ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba.

29. Nítorí àìlábámọ̀ li ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run.

Róòmù 11