Òwe 4:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹyóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10. Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

11. Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́nmo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.

12. Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀.

13. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburútàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

Òwe 4