Òwe 3:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura,òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá;àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.

Òwe 3