Òwe 2:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padàtàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rerekí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo

21. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náààwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀

22. ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náàa ó sì ya àwọn aláìsòótọ́ kúrò lórí rẹ̀.

Òwe 2