Òwe 19:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

9. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyàẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

10. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá,mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.

11. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù;fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

12. Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún,ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.

13. Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

14. A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbíṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ Olúwa ni.

15. Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọnebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

16. Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.

17. Ẹni tí ó ṣáànú talákà, Olúwa ní ó yáyóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.

18. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.

Òwe 19