Òwe 17:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sànju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

2. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.

3. Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúràṢùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.

4. Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibiòpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.

Òwe 17