Òwe 10:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

29. Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo,ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

30. A kì yóò fa Olódodo tu láéláéṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31. Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32. Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́,ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

Òwe 10