1. Báwo ni ẹṣẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà,Ìwọ ọmọbìnrin ọba!Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2. Ìdodo rẹ rí bí àwotí kì í ṣe aláìní ọtí,ìbàdí rẹ bí òkìtì àlìkámàtí a fi lílì yíká.
3. Ọmú rẹ rí bí abo àgbọ̀nrín méjìtí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4. Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín-erin.Ojú rẹ rí bí adágún ní Héṣébónìní ẹ̀bá ẹnu ìbodè Bátírábímù.Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lẹ́bánónìtí ó kọ ojú sí Dámásíkù.