Orin Sólómónì 5:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọÌwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọtí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀?

10. Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́nó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.

11. Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò

12. Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbàní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn,tí a fi wàrà wẹ̀,tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́

13. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràríti ó sun òórùn tùràrí dídùnÈtè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílìó ń kán òjíá olóòórùn dídùn

14. Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíkáAra rẹ̀ rí bí i eyín erin dídántí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

15. Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábùtí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradáraÌrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì,tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.

16. Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ó wu ni pátapáta.Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.

Orin Sólómónì 5