Orin Sólómónì 2:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,fi ojú rẹ hàn mí,jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;Nítorí tí ohùn rẹ dùn,tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

15. Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèkétí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná.

16. Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì.

17. Títí ìgbà ìtura ọjọ́títí òjìji yóò fi fò lọ,yípadà, olùfẹ́ mi,kí o sì dàbí abo egbintàbí ọmọ àgbọ̀nrínlórí òkè Bétérì.

Orin Sólómónì 2