Oníwàásù 5:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹmá sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́runỌlọ́run ń bẹ ní ọ̀runÌwọ sì wà ní ayé,nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n

3. Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìtọ́jú púpọ̀ wàbẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.

4. Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.

5. Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ.

6. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé-ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́?

Oníwàásù 5