Oníwàásù 1:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Aṣán! Aṣán!”ni oníwàásù wí pé“Aṣán pátapáta!Gbogbo rẹ̀ aṣán ni”

3. Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4. Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5. Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.

6. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù,Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

Oníwàásù 1