Onídájọ́ 3:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

10. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

Onídájọ́ 3