Onídájọ́ 2:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Bálímù.

12. Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú.

13. Nítorí tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Báálì àti Ásítarótù.

14. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.

15. Nígbà-kí-ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀ta a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn, wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.

16. Olúwa gbé àwọn onídájọ́ (aṣíwájú tí ó ní agbára) dìde sí àwọn tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn.

17. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbérè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa.

Onídájọ́ 2