Onídájọ́ 17:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì kan wà, ẹni tí ó wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ẹni tí ó ti ń gbé ní àárin ẹ̀yà Júdà,

8. fi ìlú náà sílẹ̀ láti wá ibòmíràn láti máa gbé. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Míkà nínú àwọn ilẹ̀ òkè Éfúráímù.

9. Míkà bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”Ó dáhùn pé, “Ọmọ Léfì ni mí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Júdà, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”

10. Míkà sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi (máa bá mi gbé) kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.”

Onídájọ́ 17