19. Òun sì mú kí Sámúsónì sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀ (dá a lóró). Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
20. Òun pè é wí pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.”Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìn wá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀.
21. Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.
22. Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.
23. Àwọn ìjòyè, àwọn ará Fílístínì sì péjọ pọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dágónì ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Sámúsónì ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́.