Onídájọ́ 11:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jẹ́fítà ará Gílíádì jẹ́ akọni jagunjagun. Gílíádì ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ aṣẹ́wó.

2. Ìyàwó Gílíádì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jẹ́fità jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ aṣẹ́wó) ọmọ obìnrin mìíràn.”

Onídájọ́ 11