Onídájọ́ 10:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ikú Ábímélékì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Ísákárì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ní Sámírì tí ó wà ní òkè Éfúráímù ni ó gbé.

2. Ó ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́talélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Sámírì.

3. Jáírì ti ẹ̀yà Gílíádì ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Ísirẹ́lì ní ọdún méjìlélógún.

Onídájọ́ 10