Onídájọ́ 1:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun (orúkọ Débírì ní ìgbà àtijọ́ ni Kíríátì-Ṣéférì tàbí ìlú àwọn ọ̀mọ̀wé).

12. Kélẹ́bù sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.”

13. Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.

Onídájọ́ 1