Nọ́ḿbà 7:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Élíábù ọmọ Hélónì, olórí àwọn ọmọ Sébúlónì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹ́ta.

25. Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọn rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì,

26. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

27. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

Nọ́ḿbà 7