7. Lórí tabilì ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, wọn ó sì kó àwọn àwo, páànù, àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àkàrà tó sì máa ń wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.
8. Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
9. “Kí wọn kí ó fi aṣọ aláwọ̀ búlù bọ ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti àwo ìkó ẹ̀mu sí, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
10. Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.
11. “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
12. “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.
13. “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.
14. Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò. Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.