Nọ́ḿbà 4:35-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

36. Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín àádọ́ta (2,750).

37. Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kóhátì tó ń ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé; tí Mósè àti Árónì kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

38. Wọ́n ka àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ìdílé àti ile baba wọn.

Nọ́ḿbà 4