7. Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì ní éjìdínláàdọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
8. Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”
9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,
10. “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì,
11. Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sá lọ síbẹ̀.