39. Árónì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hórì.
40. Àwọn ará Kénánì, ọba Árádì, tí ń gbé ìhà gúṣù ní ilẹ̀ Kénánì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ̀.
41. Wọ́n kúrò ní orí òkè Hórì, wọ́n sì pàgọ́ ní Ṣálímónà.
42. Wọ́n kúrò ní Ṣálímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Púnónì.
43. Wọ́n kúrò ní Púnónì wọ́n sì pàgọ́ ní Óbótù.
44. Wọ́n kúrò ní Óbótù wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Ábárímù, ní agbégbé Móábù.